Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:5 - Bibeli Mimọ

5 Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:5
23 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn.


Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀.


O si ṣe iboju alaro, ati elése aluko ati òdodó, ati ọ̀gbọ daradara, o si ṣiṣẹ awọn kerubu lara wọn.


O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu.


Iwọ o si fi apoti ẹrí nì sinu rẹ̀, iwọ o si ta aṣọ-ikele ni bò apoti na.


Iwọ o si fi pẹpẹ wurà ti turari nì si iwaju apoti ẹrí, iwọ o si fi aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na sara agọ́ na.


Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède.


OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu.


Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.


Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.


Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni:


Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.


Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán;


Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.


Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;


Ati lẹhin aṣọ ikele keji, on ni agọ́ ti a npè ni ibi mimọ julọ;


On si pọn awọn ọkunrin Betṣemeṣi loju, nitoriti nwọn bẹ inu apoti Oluwa wò, iye wọn ti o pa ninu awọn enia na jẹ ẹgbã mẹdọgbọn o le ãdọrin ọkunrin, awọn enia na pohunrere ẹkun nitoriti Oluwa fi iparun nla pa ọpọ̀ awọn enia na run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan