Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:3
27 Iomraidhean Croise  

Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já.


Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.


Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.


Ati fun awọn alufa ti a kọ sinu iwe nipa ile baba wọn, ati awọn ọmọ Lefi, lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ, ninu ilana wọn, nipa ipa wọn:


Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa.


Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.


Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.


Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn;


Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn,


Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.


Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́.


Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ:


Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni:


Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ,


Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,


Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere;


OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ.


Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan