Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:25 - Bibeli Mimọ

25 Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:25
8 Iomraidhean Croise  

IWỌ o fi aṣọ-tita mẹwa ṣe agọ́ na; aṣọ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ti on ti awọn kerubu iṣẹ ọlọnà ni ki iwọ ki o ṣe wọn.


Iwọ o si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori rẹ̀.


O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.


Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù:


Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan