Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 4:12 - Bibeli Mimọ

12 Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 4:12
16 Iomraidhean Croise  

Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.


Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari.


Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun;


Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa.


Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Ọlọrun, pẹpẹ wura pẹlu, ati awọn tabili lori eyi ti akara ifihan wà;


Ati alumagaji fitila, ati awo-koto, ati ṣibi ati awo-koto turari, wura daradara ni: ati ọ̀na iwọle, awẹ ilẹkun rẹ̀ ti inu lọhun fun ibi-mimọ́-jùlọ, ati awọn ilẹkun fun ile na, ani tempili, wura ni.


Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu.


Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e.


Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa;


Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.


Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.


Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o.


Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ.


Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀:


Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan