Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:3 - Bibeli Mimọ

3 Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:3
9 Iomraidhean Croise  

Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀.


Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.


O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá.


Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.


Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin.


Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan