Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:2 - Bibeli Mimọ

2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:2
23 Iomraidhean Croise  

Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa.


Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.


Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.


Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.


Emi si wipe, Bawo li emi o ṣe gbe ọ kalẹ pẹlu awọn ọmọ, ati lati fun ọ ni ilẹ ayanfẹ, ogún daradara, ani ogún awọn orilẹ-ède? Emi si wipe, Iwọ o pè mi ni, Baba mi! iwọ kì o si pada kuro lọdọ mi.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.


Ẹnyin o si jogún rẹ̀, olukuluku bi ti ekeji rẹ̀: eyiti mo ti gbe ọwọ́ mi sokè lati fi i fun awọn baba nyin: ilẹ yi yio si bọ sọdọ nyin fun ogún.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn;


Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.


Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.


Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ,


Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.


JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.


OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan