Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:7 - Bibeli Mimọ

7 Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:7
9 Iomraidhean Croise  

Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀.


Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ.


Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru.


Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na.


Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi?


Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn.


Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa.


Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan