Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:5 - Bibeli Mimọ

5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Tí a bá rí ojúrere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:5
11 Iomraidhean Croise  

Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú.


Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ.


O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na.


Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀.


Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin.


Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi?


OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀:


Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani!


Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi?


Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan