Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:3 - Bibeli Mimọ

3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:3
22 Iomraidhean Croise  

Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani.


Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.


SI Moabu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Egbe ni fun Nebo! nitoriti a fi ṣe ijẹ: oju tì Kiriataimu, a si kó o: oju tì Misgabu, o si wariri.


Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ.


Emi o sọkun fun àjara Sibma jù ẹkùn Jaseri lọ: ẹka rẹ ti rekọja okun lọ, nwọn de okun Jaseri: afiniṣe-ijẹ yio kọlu ikore eso rẹ ati ikore eso-àjara rẹ.


Lati igbe Heṣboni de Eleale, de Jahasi, ni nwọn fọ ohùn wọn, lati Soari de Horonaimu, ti iṣe ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta, nitori omi Nimrimu pẹlu yio dahoro.


Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro.


Nitorina, kiye si i, emi o ṣi ìha Moabu kuro lati awọn ilu gbogbo, kuro ninu awọn ilu rẹ̀ ti o wà li àgbegbe rẹ̀, ogo ilẹ na, Bet-jeṣimoti, Baalimeoni, ati Kiri-ataimu,


Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni.


Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba.


Mose si rán enia lọ ṣe amí Jaseri, nwọn si gbà ilu rẹ̀, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà nibẹ̀.


NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;


Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe,


Heṣboni, ati gbogbo ilu rẹ̀ ti mbẹ ni pẹtẹlẹ̀; Diboni, ati Bamoti-baali, ati Beti-baali-meoni;


Ati Kiriataimu, ati Sibma, ati Sareti-ṣahari ni òke afonifoji na;


Heṣboni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Jaseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin ni gbogbo rẹ̀.


Nigbati Israeli fi joko ni Heṣboni ati awọn ilu rẹ̀, ati ni Aroeri ati awọn ilu rẹ̀, ati ni gbogbo awọn ilu ti o wà lọ titi de ẹba Arnoni, li ọdunrun ọdún; ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a li akokò na?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan