Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:3 - Bibeli Mimọ

3 Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:3
10 Iomraidhean Croise  

On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli.


Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.


Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ.


Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade.


Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.


Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA:


Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi.


Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori.


O si ṣe nigbati o ri i, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Yẽ, ọmọ mi! iwọ rẹ̀ mi silẹ gidigidi, iwọ si li ọkan ninu awọn ti nyọ mi lẹnu: nitori emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada.


On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan