Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:2 - Bibeli Mimọ

2 Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:2
36 Iomraidhean Croise  

Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ.


Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.


Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.


Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́.


Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀.


Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.


Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.


O ti nà ọwọ rẹ̀ si iru awọn ti o wà li alafia pẹlu rẹ̀: o ti dà majẹmu rẹ̀.


Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ.


Ẹ ṣe ileri ifẹ, ki ẹ si san a fun Oluwa, Ọlọrun nyin: jẹ ki gbogbo awọn ti o yi i ka ki o mu ẹ̀bun wá fun ẹniti a ba ma bẹ̀ru.


Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn.


Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu.


Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi:


Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.


Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata.


Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde,


Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa.


Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese.


Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese.


Nigbati ilẹ mọ́, awọn Ju kan dimọlu, nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ bẹ̃li awọn kì yio mu, titi awọn ó fi pa Paulu.


Nwọn si tọ̀ olori awọn alufa ati awọn àgbagba lọ, nwọn si wipe, Awa ti fi èpe nla bu ara wa pe, a kì yio tọ́ ohun nkan wò titi awa ó fi pa Paulu.


Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ.


Mo si pè Ọlọrun ṣe ẹlẹri li ọkàn mi pe, nitori lati dá nyin si li emi kò ṣe ti wá si Korinti.


Nigbana ni Jefta bá awọn àgba Gileadi lọ, awọn enia na si fi i jẹ́ olori ati balogun wọn: Jefta si sọ gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ niwaju OLUWA ni Mispa.


O si ṣe li opin oṣù keji, o si pada wá sọdọ baba rẹ̀, ẹniti o ṣe si i gẹgẹ bi ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́: on kò si mọ̀ ọkunrin. O si di ìlana ni Israeli pe,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan