Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:9 - Bibeli Mimọ

9 Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:9
15 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.


Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,


Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti.


Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose.


Ninu awọn Netinimu pẹlu, ti Dafidi ati awọn ijoye ti fi fun isin awọn ọmọ Lefi, ogunlugba Netinimu gbogbo wọn li a kọ orukọ wọn.


Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn;


Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.


Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.


Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi.


Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.


Emi si ti gbà awọn ọmọ Lefi dipò gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli.


Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́.


O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni;


Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan