Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:8 - Bibeli Mimọ

8 Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:8
13 Iomraidhean Croise  

Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ:


Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari.


Ẹ fà sẹhin, é fà sẹhin, é jade kuro lãrin rẹ̀; ẹ má fọwọ kàn ohun aimọ́ kan: ẹ kuro lãrin rẹ̀, ẹ jẹ mimọ́, ẹnyin ti ngbe ohun-èlo Oluwa.


A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí.


Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn.


Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.


Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.


Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA.


Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.


Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.


Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan