Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:6 - Bibeli Mimọ

6 Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 “Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:6
18 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.


Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;


Ati ki nwọn ki o ma tọju ẹṣọ agọ ajọ enia, ati ẹṣọ ibi mimọ́, ati ẹṣọ awọn ọmọ Aaroni arakunrin wọn, ni ìsin ile Oluwa.


Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,


Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari.


Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose.


Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li o ti rán ofin yi si nyin, ki majẹ̀mu mi le wà pẹlu Lefi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.


Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.


Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan