Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:51 - Bibeli Mimọ

51 Mose si fi owo awọn ti a rapada fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

51 Mose fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ní owó ìràpadà náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:51
11 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.


Ẹ ranti ofin Mose iranṣẹ mi, eyi ti mo pa li aṣẹ fun u ni Horebu fun gbogbo Israeli, pẹlu aṣẹ ati idajọ wọnni.


Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li o si kaye wọn ni ijù Sinai.


Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara.


Ki o si fi ninu owo na, ani owo ìrapada ti o lé ninu wọn, fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀.


Lọwọ awọn akọ́bi awọn ọmọ Israeli li o gbà owo na; egbeje ṣekeli o din marundilogoji, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́:


OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe,


Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni.


Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.


Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan