Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn.
Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.
Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.