Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:41 - Bibeli Mimọ

41 Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:41
10 Iomraidhean Croise  

Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ.


Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe:


Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.


Mose si kà gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, bi OLUWA ti paṣẹ fun u.


Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA.


Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.


Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.


Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan