Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:3
10 Iomraidhean Croise  

Dafidi si pín wọn ni ẹgbẹgbẹ lãrin awọn ọmọ Lefi, eyini ni Gerṣoni, Kohati, ati Merari.


Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.


Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.


Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn.


O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́.


Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.


Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.


Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan