Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:13 - Bibeli Mimọ

13 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:13
16 Iomraidhean Croise  

Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa.


Ni iwọ o si yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun OLUWA, ati gbogbo akọ́bi ẹran ti iwọ ni; ti OLUWA li awọn akọ.


O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada.


Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe.


Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi.


Gbogbo akọ́bi ni ti emi; ati akọ ninu gbogbo ohunọ̀sin rẹ; akọ́bi ti malu, ati ti agutan.


Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ.


Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni.


Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ.


Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.


Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli.


Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.


(Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;)


Si ajọ nla ati ìjọ akọbi ti a ti kọ orukọ wọn li ọ̀run, ati sọdọ Ọlọrun onidajọ gbogbo enia, ati sọdọ awọn ẹmí olõtọ enia ti a ṣe li aṣepé,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan