Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 28:3 - Bibeli Mimọ

3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 “Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 28:3
25 Iomraidhean Croise  

Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;


Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.


Lẹhin na nwọn si ru ẹbọ sisun igbagbogbo ati ti oṣu titun, ati ti gbogbo ajọ Oluwa, ti a si yà si mimọ́, ati ti olukuluku ti o fi tinu-tinu ru ẹbọ atinuwa si Oluwa.


Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ.


Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ.


Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ.


Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?


Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.


Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀.


Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta.


Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.


A o si fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ si OLUWA; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.


Ki ẹnyin ki o mú wọnyi wá pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀, ti iṣe ti ẹbọ sisun igbagbogbo.


Bayi ni ki ẹnyin rubọ li ọjọjọ́, jalẹ ni ijọ́ mejeje, onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: ki a ru u pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.


Ki ẹnyin ki o ru wọn pẹlu ẹbọ sisun igba-gbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ (ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin), ati ẹbọ ohunmimu wọn.


Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ;


Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.


Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.


Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.


Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ!


Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin.


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan