Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn.
Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa:
Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai.
Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.
Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi.
Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa.
Ati eyiti nwọn kò le ṣe alaini ẹgbọrọ akọmalu, ati àgbo, pẹlu ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun si Ọlọrun ọrun, alikama, iyọ, ọti-waini pẹlu ororo, gẹgẹ bi ilana awọn alufa ti o wà ni Jerusalemu, ki a mu fun wọn li ojojumọ laiyẹ̀:
Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa.
Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́.
Ti ọmọ-alade yio jẹ́ ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ mimu, ninu asè gbogbo, ati ni oṣù titun, ati ni awọn ọjọ isimi, ni gbogbo ajọ ile Israeli: on o pèse ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati ṣe etùtu fun ile Israeli.
Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.