Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:7 - Bibeli Mimọ

7 Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 “Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:7
10 Iomraidhean Croise  

Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn.


Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́.


Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀.


Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere.


Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si.


Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu.


Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan