Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:2 - Bibeli Mimọ

2 Nwọn si duro niwaju Mose, ati niwaju Eleasari alufa, ati niwaju awọn olori ati gbogbo ijọ, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:2
10 Iomraidhean Croise  

Ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olori alufa:


NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa.


Ki on si duro niwaju Eleasari alufa, ẹniti yio bère fun u nipa idajọ Urimu niwaju OLUWA: nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o jade lọ, ati nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o wọle, ati on, ati gbogbo awọn ọmọ Israeli pẹlu rẹ̀, ani gbogbo ijọ.


Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.


AWỌN baba àgba ti idile awọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile awọn ọmọ Josefu, sunmọtosi, nwọn si sọ niwaju Mose, ati niwaju awọn olori, awọn baba àgba awọn ọmọ Israeli:


Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan