Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:11 - Bibeli Mimọ

11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:11
7 Iomraidhean Croise  

Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.


Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada.


Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀.


Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀:


Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.


Lati ọjọ na lọ, o si pa a li aṣẹ, o si sọ ọ li ofin fun Israeli titi di oni yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan