Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:53 - Bibeli Mimọ

53 Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

53 “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:53
16 Iomraidhean Croise  

Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi:


OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.


Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.


O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na.


Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn.


Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli.


Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipa gbogbo ijọba ni gbogbo abẹ-ọrun, li a o si fi fun enia awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo, ijọba ẹniti iṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yio ma sìn, ti nwọn o si ma tẹriba fun u.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀.


Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.


Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye.


Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.


Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.


WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn,


Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.


Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa: nwọn si njọba lori ilẹ aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan