Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.
Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ.
O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀.
Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli: