Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:10 - Bibeli Mimọ

10 Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:10
15 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ Israeli si jẹ manna li ogoji ọdún, titi nwọn fi dé ilẹ ti a tẹ̀dó; nwọn jẹ manna titi nwọn fi dé àgbegbe ilẹ Kenaani.


Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná.


Emi o si dojukọ ọkunrin na, emi o si fi i ṣe àmi ati owe, emi o si ké e kuro lãrin awọn enia mi; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.


Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí:


Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli.


Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn.


Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.


Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli:


Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai:


Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun;


Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.


Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan