Numeri 24:9 - Bibeli Mimọ9 O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. Faic an caibideilYoruba Bible9 Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!” Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” Faic an caibideil |
Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.