Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:8 - Bibeli Mimọ

8 Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:8
18 Iomraidhean Croise  

Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀.


Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn.


Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ.


Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni.


Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin.


Mo ṣirò titi di òwurọ, pe, bi kiniun, bẹ̃ni yio fọ́ gbogbo egungun mi; lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi.


Israeli jẹ́ agutan ti o ṣina kiri, awọn kiniun ti le e lọ: niṣaju ọba Assiria pa a jẹ, ati nikẹhin yi Nebukadnessari, ọba Babeli, sán egungun rẹ̀.


Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.


Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu.


Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.


Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.


Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere.


Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa.


O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá.


Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lò ọfà mi tán si wọn lara:


Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá.


NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;


Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan