Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:7 - Bibeli Mimọ

7 Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀, omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀; àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu. Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ, ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:7
29 Iomraidhean Croise  

Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.


Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.


HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo.


Dafidi si woye pe, Oluwa ti fi idi on joko li ọba lori Israeli, nitori a gbé ijọba rẹ̀ ga nitori ti awọn enia rẹ̀, Israeli.


Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn.


LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀.


Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi.


Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá.


Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i.


Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ.


Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀.


Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó.


GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo.


Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.


Iwọ ẹniti ngbe ẹba omi pupọ, ti o pọ ni iṣura, opin rẹ de, iwọn ikogun-ole rẹ kún.


Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai.


Nigbati o si wò Amaleki, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Amaleki ni ekini ninu awọn orilẹ-ède; ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ ni ki o ṣegbé.


Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli.


Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai.


ỌKAN ninu awọn angẹli meje na ti o ni ìgo meje wọnni si wá, o si ba mi sọrọ wipe, Wá nihin; emi o si fi idajọ àgbere nla nì ti o joko lori omi pupọ̀ han ọ:


O si wi fun mi pe, Awọn omi ti iwọ ri nì, nibiti àgbere nì joko, awọn enia ati ẹya ati orilẹ ati oniruru ède ni wọn.


O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan