Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:6 - Bibeli Mimọ

6 Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ, bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò. Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn, ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:6
16 Iomraidhean Croise  

Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.


Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede.


Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn.


Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀.


Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi.


Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù.


Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán.


Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.


Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara.


Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.


Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.


Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan