Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:4 - Bibeli Mimọ

4 Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:4
20 Iomraidhean Croise  

LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi.


O si ṣe nigbati õrùn nwọ̀ lọ, orun ìjika kùn Abramu; si kiyesi i, ẹ̀ru bà a, òkunkun biribiri si bò o.


On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.


Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia.


Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.


O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.


Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe.


Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ.


O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi:


Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli!


Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,


Bi Peteru si ti nronu iran na, Ẹmí wi fun u pe, Wo o, awọn ọkunrin mẹta nwá ọ.


O si ṣe pe, nigbati mo pada wá si Jerusalemu, ti mo ngbadura ni tẹmpili mo bọ si ojuran;


Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè,


Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin:


On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan