Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:3 - Bibeli Mimọ

3 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:3
9 Iomraidhean Croise  

On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.


On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀.


PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe,


Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ.


O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu:


O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.


O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi:


Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí:


Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan