Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:14 - Bibeli Mimọ

14 Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:14
16 Iomraidhean Croise  

JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin.


A o si ko wọn jọ pọ̀, bi a iti kó ara tubu jọ sinu ihò, a o tì wọn sinu tubu, lẹhin ọjọ pupọ̀ li a o si bẹ̀ wọn wò.


Sibẹ emi o tun mu igbekun Moabu pada li ọjọ ikẹhin, li Oluwa wi. Titi de ihin ni idajọ Moabu.


Ṣugbọn yio si ṣe, ni ikẹhin ọjọ, emi o tun mu igbèkun Elamu pada, li Oluwa wi.


Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe.


Ṣugbọn Ọlọrun kan mbẹ li ọrun ti o nfi aṣiri hàn, ẹniti o si fi hàn fun Nebukadnessari ohun ti mbọ wá ṣe ni ikẹhin ọjọ. Alá rẹ, ati iran ori rẹ lori akete rẹ, ni wọnyi;


Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.


Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.


Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.


Balaamu si dide, o si lọ o si pada si ibujoko rẹ̀; Balaki pẹlu si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.


Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá:


ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de.


Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa.


Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.


Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan