Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:10 - Bibeli Mimọ

10 Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:10
15 Iomraidhean Croise  

Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun.


Awọn enia yio si ṣapẹ si i lori, nwọn o si ṣe ṣiọ si i kuro ni ipò rẹ̀.


Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ.


Emi o si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, emi o si jẹ ki irúnu mi ki o simi: emi Oluwa li o ti wi bẹ̃.


Kiyesi i, nitorina, mo ti fi ọwọ́ lu ọwọ̀ pọ̀ si ère aiṣõtọ rẹ ti o ti jẹ, ati si ẹjẹ rẹ ti o ti wà lãrin rẹ.


Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.


Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi.


Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú.


Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata.


Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá.


O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú.


Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun.


Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan