Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:1 - Bibeli Mimọ

1 NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:1
13 Iomraidhean Croise  

Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ.


Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u.


On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi.


Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i.


Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe!


Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù.


Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan.


Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.


Kiyesi i, nipaṣe ọ̀rọ Balaamu awọn wọnyi li o mu awọn ọmọ Israeli dẹ̀ṣẹ si OLUWA niti ọ̀ran Peori, ti àrun si fi wà ninu ijọ OLUWA.


Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere.


Wõ, emi mọ̀ nisisiyi pe, nitotọ iwọ o jẹ ọba, ilẹ-ọba Israeli yio si fi idi mulẹ si ọ lọwọ.


Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi.


Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan