Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:9 - Bibeli Mimọ

9 Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Mo rí wọn láti òkè gíga, mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé; wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:9
15 Iomraidhean Croise  

Nitoripe nwọn mu awọn ọmọ wọn obinrin fun aya wọn, ati fun awọn ọmọ wọn ọkunrin: tobẹ̃ ti a da iru-ọmọ mimọ́ pọ̀ mọ awọn enia ilẹ wọnni: ọwọ awọn ijoye, ati awọn olori si ni pataki ninu irekọja yi.


Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si.


Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ?


Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.


Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀.


Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ.


Fi ọpa rẹ bọ́ enia agbo ini rẹ, ti ndágbe inu igbó lãrin Karmeli: jẹ ki wọn jẹ̀ ni Baṣani ati Gileadi, bi ọjọ igbãni.


Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.


Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli.


Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ.


Ẹniti o fi ara rẹ̀ fun wa, ki on ki o le rà wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ gbogbo, ki o si le wẹ awọn enia kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ini on tíkararẹ awọn onitara iṣẹ rere.


Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan