Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:3 - Bibeli Mimọ

3 Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:3
16 Iomraidhean Croise  

Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀.


O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.


Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na.


Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun.


OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe,


On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?


On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi.


Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.


Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?


Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.


NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.


Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a;


Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan