Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:7 - Bibeli Mimọ

7 Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:7
15 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.


Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.


Ẹnyin o ha si bà mi jẹ lãrin awọn enia mi nitori ikunwọ ọkà bàba, ati nitori òkele onjẹ, lati pa ọkàn ti kì ba kú, ati lati gba awọn ọkàn ti kì ba wà lãye là, nipa ṣiṣeke fun awọn enia mi ti ngbọ́ eke nyin?


Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ.


Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.


O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu.


Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe!


NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.


Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.


Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.


Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa.


Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo;


Egbé ni fun wọn! Nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan