Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:5 - Bibeli Mimọ

5 O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé: “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:5
15 Iomraidhean Croise  

Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu.


O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ.


Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti.


Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.


O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.


Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa.


Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú.


Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ.


Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa.


Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú:


Egbé ni fun wọn! Nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.


Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan