Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:4 - Bibeli Mimọ

4 Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:4
13 Iomraidhean Croise  

Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.


Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu.


Ẹkún nlanla ni yio wà lori gbogbo orule Moabu, ati ni ita rẹ̀: nitori emi ti fọ́ Moabu bi ati ifọ́ ohun-elo, ti kò wù ni, li Oluwa wi.


Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori.


Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u.


Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.


Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa.


Njẹ iwọ ha san jù Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu? on ha bá Israeli ṣe gbolohùn asọ̀ rí, tabi o ha bá wọn jà rí?


AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan