Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:1 - Bibeli Mimọ

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:1
14 Iomraidhean Croise  

Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn;


Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.


Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe,


Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.


Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn.


Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.


OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,


Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.


Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe,


Nigbana li awa gbà li ọwọ́ awọn ọba ọmọ Amori mejeji, ilẹ ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani, lati afonifoji Arnoni lọ dé òke Hermoni;


MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a;


Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari.


Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan