Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:6 - Bibeli Mimọ

6 OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:6
8 Iomraidhean Croise  

Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò.


Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère.


Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi.


Bi mo ba jẹ ki ẹranko buburu kọja lãrin ilẹ na, ti nwọn si bà a jẹ, tobẹ̃ ti o di ahoro, ti ẹnikan kò le là a ja nitori awọn ẹranko na.


Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn.


Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan