Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:3 - Bibeli Mimọ

3 OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:3
11 Iomraidhean Croise  

Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i.


Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn.


EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi.


On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u.


Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.


Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma.


Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí:


Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;


Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma;


Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma.


Ati si awọn ti o wà ni Homa, ati si awọn ti o wà ni Koraṣani, ati si awọn ti o wà ni Ataki.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan