O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.
Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu.