Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:5 - Bibeli Mimọ

5 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:5
8 Iomraidhean Croise  

Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú.


Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si.


Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.


Gẹgẹ bi mo ti dá awọn baba nyin lẹjọ li aginju ilẹ Egipti, bẹ̃ni emi o bá nyin rojọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Pẹlupẹlu iwọ kò ti imú wa dé ilẹ kan ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bẹ̃ni iwọ kò fun wa ni iní ilẹ ati ọgba-àjara: iwọ o yọ oju awọn ọkunrin wọnyi bi? awa ki yio gòke wá.


A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba.


Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.)


Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan