Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:10 - Bibeli Mimọ

10 Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:10
18 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi.


Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.


O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla.


Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli.


A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba.


Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi.


Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.


Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin:


Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin.


Nitori ninu ohun pipọ ni gbogbo wa nṣì i ṣe. Bi ẹnikan kò ba ṣì i ṣe ninu ọ̀rọ, on na li ẹni pipé, on li o si le kó gbogbo ara ni ijanu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan