Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:1 - Bibeli Mimọ

1 AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:1
23 Iomraidhean Croise  

Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu.


Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi.


Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó.


Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na.


Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ?


Ati ihà gusu si gusu, lati Tamari titi de omi ijà ni Kadeṣi, pẹ̀tẹlẹ si okun nla. Eyi ni ihà gusu.


Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.


A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo.


Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ.


A si sé Miriamu mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje: awọn enia kò si ṣí titi a fi gbà Miriamu pada.


Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.


Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.


Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:


Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori.


Mose si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀; Aaroni si kú nibẹ̀ li ori òke na: Mose ati Eleasari si sọkalẹ lati ori òke na wá.


Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.


Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.)


Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi),


Ẹnyin si joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pupọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.


Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.


Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli.


Ṣugbọn nigbati Israeli gòke ti Egipti wá, ti nwọn si nrìn li aginjù, titi dé Okun Pupa, ti nwọn si dé Kadeṣi;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan