Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:3 - Bibeli Mimọ

3 Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:3
19 Iomraidhean Croise  

O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila.


Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni.


Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;


Nitori Juda bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wá; ṣugbọn ogún ibi jẹ ti Josefu:)


Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u.


Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.


Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.


Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju.


Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta.


Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a.


Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.


Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu.


Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni;


Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan