Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:18 - Bibeli Mimọ

18 Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:18
13 Iomraidhean Croise  

Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.


Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi.


Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru.


Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;


Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀.


Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.


Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu:


Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu.


Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan